Esekiẹli 47:18
Ezekiel 47:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ìhà ìlà-oòrùn ààlà yóò wá sí àárín Haurani àti Damasku, lọ sí apá Jordani láàrín Gileadi àti ilẹ̀ Israẹli, títí dé Òkun, àti títí dé Tamari. Èyí ní yóò jẹ́ ààlà ìlà-oòrùn.
Ezekiel 47:18 in English
Ezekiel 47:18 · Berean Standard Bible
On the east side the border will run between Hauran and Damascus, along the Jordan between Gilead and the land of Israel, to the Eastern Sea and as far as Tamar.* This will be the eastern boundary.
Context
16Berota àti Sibraimu, èyí tí ó wà ní ààlà láàrín Damasku àti Hamati títí dé Hasari Hatikonu, èyí tí ó wà ní agbègbè Haurani. 17Ààlà yóò fẹ̀ láti Òkun lọ sí Hasari Enanu, ní apá ààlà ti Damasku, pẹ̀lú ààlà tí Hamati lọ sí apá àríwá. Èyí ni yóò jẹ́ ààlà ní apá ìhà àríwá. 18Ní ìhà ìlà-oòrùn ààlà yóò wá sí àárín Haurani àti Damasku, lọ sí apá Jordani láàrín Gileadi àti ilẹ̀ Israẹli, títí dé Òkun, àti títí dé Tamari. Èyí ní yóò jẹ́ ààlà ìlà-oòrùn. 19Ní ìhà gúúsù yóò lọ láti Tamari títí dé ibi omi Meriba Kadeṣi, lẹ́yìn náà ni ìhà Wadi tí Ejibiti lọ sí Òkun ńlá. Èyí ni yóò jẹ́ ààlà gúúsù. 20Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, Òkun ńlá ni yóò jẹ́ ààlà títí dé ibi kan ni òdìkejì lẹ́bàá Hamati. Èyí yìí ni yóò jẹ ààlà ìhà ìwọ̀-oòrùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.