Esekiẹli 44:18
Ezekiel 44:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n yóò sì dé fìlà ọ̀gbọ̀ sí orí wọn àti ṣòkòtò ọ̀gbọ̀ sí ìdí wọn. Wọn kò sì gbọdọ̀ wọ ohunkóhun tí yóò mú wọn làágùn.
Ezekiel 44:18 in English
Ezekiel 44:18 · Berean Standard Bible
They are to wear linen turbans on their heads and linen undergarments around their waists. They must not wear anything that makes them perspire.
Context
16Àwọn nìkan ni ó gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi; àwọn nìkan ní o gbọdọ̀ súnmọ́ tábìlì mi láti ṣe ìránṣẹ́ ni iwájú mi, ki wọn sì ṣe iṣẹ́ ìsìn mi. 17“ ‘Nígbà ti wọ́n wọ àwọn ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú, wọn yóò wọ ẹ̀wù ọ̀gbọ̀, wọn kò gbọdọ̀ wọ aṣọ onírun nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní àwọn ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú tàbí ni inú ilé Ọlọ́run. 18Wọ́n yóò sì dé fìlà ọ̀gbọ̀ sí orí wọn àti ṣòkòtò ọ̀gbọ̀ sí ìdí wọn. Wọn kò sì gbọdọ̀ wọ ohunkóhun tí yóò mú wọn làágùn. 19Nígbà tí wọ́n bá lọ sì àgbàlá òde níbi tí àwọn ènìyàn wà, wọn gbọdọ̀ bọ́ ẹ̀wù tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́, ki wọn sì fi wọn sílẹ̀ sí àwọn yàrá mímọ́ náà, kí wọn kí ó sì wọ ẹ̀wù mìíràn, wọn kì yóò sì fi ẹ̀wù wọn sọ àwọn ènìyàn di mímọ́. 20“ ‘Wọn kò gbọdọ̀ fá irun, wọn kò sì gbọdọ̀ jẹ́ kí irun wọn gùn, ṣùgbọ́n wọn gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí wọn wà ní gígẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.