Native Bible

Ezekiel 44:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Àwọn Lefi tí wọn rìn jìnnà kúrò lọ́dọ̀ mi nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣìnà, ti wọ́n sì ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi láti tọ àwọn ère wọn lẹ́yìn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Ezekiel 44:10 in English

Ezekiel 44:10 · Berean Standard Bible

Surely the Levites who wandered away from Me when Israel went astray, and who wandered away from Me after their idols, will bear the consequences of their iniquity.

Context

8Dípò kí ìwọ pa òfin mi mọ́, ìwọ fi àwọn mìíràn sí ibi mímọ́ mi. 9Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Àjèjì aláìkọlà àyà àti ara kò gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi, àti pẹ̀lú àwọn àjèjì tí ń gbé ní àárín àwọn ọmọ Israẹli. 10“ ‘Àwọn Lefi tí wọn rìn jìnnà kúrò lọ́dọ̀ mi nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣìnà, ti wọ́n sì ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi láti tọ àwọn ère wọn lẹ́yìn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 11Wọn le sìn mi ní ibi mímọ́ mi, kí wọn ṣe ìtọ́jú àwọn ẹnu-ọ̀nà ilé Ọlọ́run, kí wọn sì ṣe ìránṣẹ́ nínú rẹ̀; wọn le pa ẹbọ sísun, ki wọn sì rú ẹbọ fún àwọn ènìyàn, kí wọn sì dúró níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. 12Ṣùgbọ́n nítorí pé wọn ṣe ìránṣẹ́ fún wọn níwájú àwọn ère wọn, tí wọn sì mu ilé Israẹli ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí náà, Èmi tí búra nípa nína ọwọ́ sókè pé, wọn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ní Olúwa Olódùmarè wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.