Esekiẹli 43:18
Ezekiel 43:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ìwọ̀nyí yóò jẹ́ òfin fún ìrúbọ ẹbọ sísun àti wíwọ̀n ẹ̀jẹ̀ sórí pẹpẹ nígbà tí a bá mọ pẹpẹ tán.
Ezekiel 43:18 in English
Ezekiel 43:18 · Berean Standard Bible
Then He said to me: “Son of man, this is what the Lord GOD says: ‘These are the statutes for the altar on the day it is constructed, so that burnt offerings may be sacrificed on it and blood may be sprinkled on it:
Context
16Ibi ìdáná pẹpẹ náà jẹ́ igun mẹ́rin mẹ́rin lọ́gbọọgba, ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní gígùn, o sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní ìbú. 17Igun ni apá òkè náà jẹ́ igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní gígùn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní ìbú, pẹ̀lú etí tí ó jẹ́ ìdajì ìgbọ̀nwọ́, ìsàlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan yípo. Àtẹ̀gùn pẹpẹ ìrúbọ náà dojúkọ ìlà-oòrùn.” 18Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ìwọ̀nyí yóò jẹ́ òfin fún ìrúbọ ẹbọ sísun àti wíwọ̀n ẹ̀jẹ̀ sórí pẹpẹ nígbà tí a bá mọ pẹpẹ tán. 19Ẹ̀yin ní láti mú ọ̀dọ́ akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrékọjá fún àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Lefi, tí ìdílé Sadoku tí ó wá sí agbègbè láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún mi ní Olúwa Olódùmarè wí. 20Ẹ ni láti mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí ẹ sì fi sórí ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà lórí pẹpẹ, àti lórí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ìjókòó náà àti sí gbogbo etí rẹ̀ yípo, ìwọ yóò sì sọ pẹpẹ di mímọ́, ìwọ yóò sì ṣe ètùtù rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.