Native Bible

Ezekiel 43:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ìwọ̀nyí ni wíwọ̀n pẹpẹ ìrúbọ ní gígùn ìgbọ̀nwọ́, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni jíjìn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni ìbú, igun rẹ̀ yípo àti etí rẹ̀ jẹ́ ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan. Èyí yìí sì ni gíga pẹpẹ ìrúbọ náà.

Ezekiel 43:13 in English

Ezekiel 43:13 · Berean Standard Bible

These are the measurements of the altar in long cubits * (a cubit and a handbreadth): Its gutter shall be a cubit deep and a cubit wide, with a rim of one span * around its edge. And this is the height of the altar:

Context

11tí ojú gbogbo ohun tí wọn ti ṣe bá tì wọ́n, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ àwòrán ilé Ọlọ́run náà bí wọ́n ṣe tò ó lẹ́sẹẹsẹ, àbájáde àti àbáwọlé rẹ̀ gbogbo àwòrán àti gbogbo òfin àti ìlànà rẹ̀. Kọ ìwọ̀nyí sílẹ̀ ní iwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ́ olóòtítọ́ si àwòrán rẹ̀, kí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀. 12“Èyí yìí ní òfin ilé Ọlọ́run náà. Gbogbo àyíká lórí òkè gíga ní yóò jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ. Bí èyí ni òfin tẹmpili náà. 13“Ìwọ̀nyí ni wíwọ̀n pẹpẹ ìrúbọ ní gígùn ìgbọ̀nwọ́, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni jíjìn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni ìbú, igun rẹ̀ yípo àti etí rẹ̀ jẹ́ ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan. Èyí yìí sì ni gíga pẹpẹ ìrúbọ náà. 14Láti ìsàlẹ̀ rẹ̀ ni ilẹ̀ títí dé ìsàlẹ̀ igun rẹ̀, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga o sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ní ìbú. Láti igun rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ títí dé igun rẹ̀ ti òkè tí ó yípo pẹpẹ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gíga, igun náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ní ìbú. 15Ibi ìdáná pẹpẹ ìrúbọ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gíga, ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì yọrí jáde sókè láti ibi ìdáná.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.