Native Bible

Ezekiel 43:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

tí ojú gbogbo ohun tí wọn ti ṣe bá tì wọ́n, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ àwòrán ilé Ọlọ́run náà bí wọ́n ṣe tò ó lẹ́sẹẹsẹ, àbájáde àti àbáwọlé rẹ̀ gbogbo àwòrán àti gbogbo òfin àti ìlànà rẹ̀. Kọ ìwọ̀nyí sílẹ̀ ní iwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ́ olóòtítọ́ si àwòrán rẹ̀, kí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀.

Ezekiel 43:11 in English

Ezekiel 43:11 · Berean Standard Bible

and if they are ashamed * of all they have done, then make known to them the design of the temple—its arrangement and its exits and entrances—its whole design along with all its statutes, forms, and laws. Write it down in their sight, so that they may keep its complete design and all its statutes and may carry them out.

Context

9Nísinsin yìí jẹ́ kí wọn mú ìwà àgbèrè wọn àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn ọba wọn kúrò ni iwájú mi, èmi yóò sì gbé àárín wọn láéláé. 10“Ọmọ ènìyàn, ṣàpèjúwe ilé Ọlọ́run náà fún àwọn ènìyàn Israẹli kí ojú ẹ̀ṣẹ̀ wọn, lè tì wọ́n sì jẹ́ kí wọn wo àwòrán ilé náà, 11tí ojú gbogbo ohun tí wọn ti ṣe bá tì wọ́n, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ àwòrán ilé Ọlọ́run náà bí wọ́n ṣe tò ó lẹ́sẹẹsẹ, àbájáde àti àbáwọlé rẹ̀ gbogbo àwòrán àti gbogbo òfin àti ìlànà rẹ̀. Kọ ìwọ̀nyí sílẹ̀ ní iwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ́ olóòtítọ́ si àwòrán rẹ̀, kí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀. 12“Èyí yìí ní òfin ilé Ọlọ́run náà. Gbogbo àyíká lórí òkè gíga ní yóò jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ. Bí èyí ni òfin tẹmpili náà. 13“Ìwọ̀nyí ni wíwọ̀n pẹpẹ ìrúbọ ní gígùn ìgbọ̀nwọ́, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni jíjìn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni ìbú, igun rẹ̀ yípo àti etí rẹ̀ jẹ́ ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan. Èyí yìí sì ni gíga pẹpẹ ìrúbọ náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.