Esekiẹli 40:16
Ezekiel 40:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ni a tẹ nínú yíká; àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ní fèrèsé tóóró tí ó wọ inú yíká. Àwọn ògiri wọn ní inú ni a fi pákó tẹ yíká láti ilẹ̀ dé òkè fèrèsé àti láti fèrèsé dé òrùlé.
Ezekiel 40:16 in English
Ezekiel 40:16 · Berean Standard Bible
The gate chambers and their side pillars * had beveled windows all around the inside of the gateway. The porticos also had windows all around on the inside. Each side pillar was decorated with palm trees.
Context
14Ó sí ṣe àtẹ́rígbà ọlọ́gọ́ta ìgbọ̀nwọ́, àní títí dé àtẹ́rígbà ògiri àgbàlá, yí ẹnu-ọ̀nà ká. 15Láti iwájú ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé títí dé ìparí yàrá kéékèèké náà àti àwọn ìgbéró ògiri nínú ẹnu-ọ̀nà ní a gbé dá jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́. 16Ni a tẹ nínú yíká; àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ní fèrèsé tóóró tí ó wọ inú yíká. Àwọn ògiri wọn ní inú ni a fi pákó tẹ yíká láti ilẹ̀ dé òkè fèrèsé àti láti fèrèsé dé òrùlé. 17Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ojú òde àgbàlá. Níbẹ̀ mo rí yàrá díẹ̀ àti pèpéle tí a kọ́ yí àgbàlá ká; ọgbọ̀n yàrá wà lẹ́gbẹ̀ pèpéle náà. 18O ṣe ààlà sí ẹ̀gbẹ́ àwọn ẹnu-ọ̀nà, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà pẹ̀lú gígùn rẹ̀: èyí jẹ́ pèpéle tí ìsàlẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.