Native Bible

Ezekiel 40:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn ni àwọn yàrá kéékèèké mẹ́ta wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan: mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kọ̀ jú sí ara wọn, ojú ìgbéró ògiri ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ bákan náà ní wíwọ̀n.

Ezekiel 40:10 in English

Ezekiel 40:10 · Berean Standard Bible

There were three gate chambers on each side of the east gate, each with the same measurements, and the gateposts on either side also had the same measurements.

Context

8Lẹ́yìn náà, ó wọ̀n ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà: 9Ó jẹ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ ní jíjìn àtẹ́rígbà rẹ̀ sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ méjì ní nínípọn. Ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà kọjú sí tẹmpili. 10Ní ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn ni àwọn yàrá kéékèèké mẹ́ta wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan: mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kọ̀ jú sí ara wọn, ojú ìgbéró ògiri ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ bákan náà ní wíwọ̀n. 11Lẹ́yìn náà ó wọn ìbú à bá wọ ẹnu-ọ̀nà náà; ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, gígùn rẹ̀ sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́tàlá. 12Ní iwájú ọ̀kọ̀ọ̀kan yàrá kéékèèké kọ̀ọ̀kan ní ògiri tí gíga rẹ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan wà, ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àwọn yàrá kéékèèké sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.