Native Bible

Ezekiel 4:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ dojúkọ ìgbógunti Jerusalẹmu, na ọwọ́ rẹ sí i, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìlú náà.

Ezekiel 4:7 in English

Ezekiel 4:7 · Berean Standard Bible

You must turn your face toward the siege of Jerusalem with your arm bared, and prophesy against it.

Context

5Nítorí mo fi iye ọdún tí wọ́n fi ṣẹ̀ fún ọ gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ tí ìwọ yóò lò. Nítorí náà, ìwọ yóò ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390). 6“Tí o bá parí èyí, tún fi ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún dùbúlẹ̀ kí o sì ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda fún ogójì ọjọ́, nítorí pé ọjọ́ kan ló dúró fún ọdún kan. 7Ìwọ dojúkọ ìgbógunti Jerusalẹmu, na ọwọ́ rẹ sí i, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìlú náà. 8Èmi yóò dè ọ́ ní okùn dé bi pé ìwọ kò ní í le yírapadà láti ìhà ọ̀tún sí ìhà òsì títí tí ọjọ́ ìgbóguntì rẹ yóò fi pé. 9“Mú alikama, ọkà bàbà àti barle, erèé àti lẹntili, jéró àti ẹwẹ; fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe àkàrà tí ìwọ yóò máa jẹ nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀ fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390).

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.