Esekiẹli 4:3
Ezekiel 4:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí o sì fi àwo irin kan ṣe ògiri láàrín rẹ̀ àti ìlú yìí, kí o sì kọjú sí i, a ó sì dó tì í, ìwọ yóò sì dó tì í. Èyí yóò jẹ́ àmì fún ilé Israẹli.
Ezekiel 4:3 in English
Ezekiel 4:3 · Berean Standard Bible
Then take an iron plate and set it up as an iron wall between yourself and the city. Turn your face toward it so that it is under siege, and besiege it. This will be a sign to the house of Israel.
Context
1“Nísinsin yìí, ìwọ ọmọ ènìyàn, mú amọ̀ ṣíṣù kan, gbé e sí iwájú rẹ, kí o sì ya àwòrán ìlú Jerusalẹmu sí orí rẹ̀. 2Kí o sì dó tì í, kí o sì mọ ilé ìṣọ́ tì í, kí o sì mọ odi tì í, kí o sì gbé ogun sí i, kí o sì to òòlù yí i ká. 3Kí o sì fi àwo irin kan ṣe ògiri láàrín rẹ̀ àti ìlú yìí, kí o sì kọjú sí i, a ó sì dó tì í, ìwọ yóò sì dó tì í. Èyí yóò jẹ́ àmì fún ilé Israẹli. 4“Lẹ́yìn èyí, lọ fi ẹ̀gbẹ́ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli lé orí ara rẹ. Iye ọjọ́ tí ìwọ bá fi sùn náà ni ìwọ yóò fi ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 5Nítorí mo fi iye ọdún tí wọ́n fi ṣẹ̀ fún ọ gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ tí ìwọ yóò lò. Nítorí náà, ìwọ yóò ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390).
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.