Native Bible

Ezekiel 4:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí o sì dó tì í, kí o sì mọ ilé ìṣọ́ tì í, kí o sì mọ odi tì í, kí o sì gbé ogun sí i, kí o sì to òòlù yí i ká.

Ezekiel 4:2 in English

Ezekiel 4:2 · Berean Standard Bible

Then lay siege against it: Construct a siege wall, build a ramp to it, set up camps against it, and place battering rams around it on all sides.

Context

1“Nísinsin yìí, ìwọ ọmọ ènìyàn, mú amọ̀ ṣíṣù kan, gbé e sí iwájú rẹ, kí o sì ya àwòrán ìlú Jerusalẹmu sí orí rẹ̀. 2Kí o sì dó tì í, kí o sì mọ ilé ìṣọ́ tì í, kí o sì mọ odi tì í, kí o sì gbé ogun sí i, kí o sì to òòlù yí i ká. 3Kí o sì fi àwo irin kan ṣe ògiri láàrín rẹ̀ àti ìlú yìí, kí o sì kọjú sí i, a ó sì dó tì í, ìwọ yóò sì dó tì í. Èyí yóò jẹ́ àmì fún ilé Israẹli. 4“Lẹ́yìn èyí, lọ fi ẹ̀gbẹ́ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli lé orí ara rẹ. Iye ọjọ́ tí ìwọ bá fi sùn náà ni ìwọ yóò fi ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.