Esekiẹli 38:21
Ezekiel 38:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò fa idà yọ ni ìlòdì sí Gogu ní orí gbogbo àwọn òkè gíga mi ni Olúwa Olódùmarè wí. Idà gbogbo ènìyàn yóò lòdì sí arákùnrin rẹ̀.
Ezekiel 38:21 in English
Ezekiel 38:21 · Berean Standard Bible
And I will summon a sword against Gog on all My mountains, declares the Lord GOD, and every man’s sword will be against his brother.
Context
19Ní ìtara mi àti ní gbígbóná ìbínú mi, mo tẹnumọ́ ọn pé; ní àsìkò náà ilẹ̀ mímì tí ó lágbára ní ilẹ̀ Israẹli yóò ṣẹlẹ̀. 20Ẹja inú Òkun, àwọn ẹyẹ òfúrufú, àwọn ẹranko igbó, àti gbogbo ẹ̀dá tí ó ń rìn lórí ilẹ̀ yóò wárìrì fún ìfarahàn mi. A yóò yí òkè gíga po, àwọn bèbè òkúta ni àwa yóò fọ́ sí wẹ́wẹ́, gbogbo ògiri ni yóò wó palẹ̀. 21Èmi yóò fa idà yọ ni ìlòdì sí Gogu ní orí gbogbo àwọn òkè gíga mi ni Olúwa Olódùmarè wí. Idà gbogbo ènìyàn yóò lòdì sí arákùnrin rẹ̀. 22Èmi yóò gbé ìdájọ́ mi jáde lórí rẹ̀ pẹ̀lú ìyọnu àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀, Èmi yóò dá àgbàrá òjò, òkúta yìnyín àti imí-ọjọ́ tí ń jó lé e lórí àti lórí ọ̀wọ́ ogun àti lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ̀. 23Nítorí náà, Èmi yóò fi títóbi mi àti ìjẹ́-mímọ́ mi hàn, Èmi yóò sì fi ara mi hàn ní ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.