Esekiẹli 37:10
Ezekiel 37:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, mo sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pa á láṣẹ fún mi, èémí sì wọ inú wọn; wọ́n di alààyè, wọ́n sì dìde dúró lórí ẹsẹ̀ wọn—pẹ̀lú ìhámọ́ra tí ó pọ̀.
Ezekiel 37:10 in English
Ezekiel 37:10 · Berean Standard Bible
So I prophesied as He had commanded me, and the breath entered them, and they came to life and stood on their feet—a vast army.
Context
8Mo wò ó, iṣan ara àti ẹran-ara farahàn lára wọn, awọ ara sì bò wọ́n, ṣùgbọ́n kò sí èémí nínú wọn. 9Lẹ́yìn náà ni ó sọ fún mi pé, “Sọtẹ́lẹ̀ sí èémí; sọtẹ́lẹ̀, ọmọ ènìyàn, kí ó sì sọ fún un pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: wá láti atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ìwọ èémí, kí ó sì mí èémí sínú àwọn tí a pa wọ̀nyí, kí wọn kí ó lè wà ní ààyè.’ ” 10Nítorí náà, mo sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pa á láṣẹ fún mi, èémí sì wọ inú wọn; wọ́n di alààyè, wọ́n sì dìde dúró lórí ẹsẹ̀ wọn—pẹ̀lú ìhámọ́ra tí ó pọ̀. 11Lẹ́yìn náà ó sọ fún mi: “Ọmọ ènìyàn, àwọn egungun wọ̀nyí ni gbogbo ìdílé Israẹli. Wọ́n sọ wí pé, ‘Egungun wa ti gbẹ ìrètí wa sì ti lọ; a ti gé wa kúrò.’ 12Nítorí náà sọtẹ́lẹ̀, kí o sì sọ fun wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ: Ẹ̀yin ènìyàn mi, Èmi yóò ṣí àwọn ibojì yín, èmi yóò sì mú yín wá si ilẹ̀ Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.