Esekiẹli 36:34
Ezekiel 36:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ilẹ̀ ahoro náà ní àwa yóò tún kọ́ ti kì yóò wà ní ahoro lójú àwọn tí ó ń gba ibẹ̀ kọjá mọ́.
Ezekiel 36:34 in English
Ezekiel 36:34 · Berean Standard Bible
The desolate land will be cultivated instead of lying desolate in the sight of all who pass through.
Context
32Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ń kò ṣe nǹkan wọ̀nyí nítorí yín, ni Olúwa Olódùmarè wí. Jẹ kí ojú kí ó tì yín, kí ẹ sì gba ẹ̀tẹ́ nítorí ìwà yín ẹ̀yin ilé Israẹli! 33“ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ tí mo wẹ̀ yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo, èmi yóò ṣe àtúnṣe àwọn ìlú yín, wọn yóò sì ṣe àtúnkọ́ ìwólulẹ̀. 34Ilẹ̀ ahoro náà ní àwa yóò tún kọ́ ti kì yóò wà ní ahoro lójú àwọn tí ó ń gba ibẹ̀ kọjá mọ́. 35Wọn yóò sọ wí pé, “Ilẹ̀ yìí tí ó ti wà ní ahoro tẹ́lẹ̀ ti dàbí ọgbà Edeni; àwọn ìlú tí ó wà ní wíwó lulẹ̀, ahoro tí a ti parun, ni àwa yóò mọdi sí tí yóò sì wà fún gbígbé ni ìsinsin yìí.” 36Nígbà náà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká yín tí ó kù yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa ti tún àwọn ohun tí ó bàjẹ́ kọ́, mo sì ti tún ohun tí ó di ìṣòfo gbìn. Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, èmi yóò sì ṣe e?’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.