Native Bible

Ezekiel 36:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ tí mo wẹ̀ yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo, èmi yóò ṣe àtúnṣe àwọn ìlú yín, wọn yóò sì ṣe àtúnkọ́ ìwólulẹ̀.

Ezekiel 36:33 in English

Ezekiel 36:33 · Berean Standard Bible

This is what the Lord GOD says: On the day I cleanse you from all your iniquities, I will cause the cities to be resettled and the ruins to be rebuilt.

Context

31Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rántí àwọn ọ̀nà búburú àti àwọn ìwà ìkà yín, ẹ̀yin yóò sì kórìíra ara yín fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ìwà tí kò bójúmu. 32Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ń kò ṣe nǹkan wọ̀nyí nítorí yín, ni Olúwa Olódùmarè wí. Jẹ kí ojú kí ó tì yín, kí ẹ sì gba ẹ̀tẹ́ nítorí ìwà yín ẹ̀yin ilé Israẹli! 33“ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ tí mo wẹ̀ yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo, èmi yóò ṣe àtúnṣe àwọn ìlú yín, wọn yóò sì ṣe àtúnkọ́ ìwólulẹ̀. 34Ilẹ̀ ahoro náà ní àwa yóò tún kọ́ ti kì yóò wà ní ahoro lójú àwọn tí ó ń gba ibẹ̀ kọjá mọ́. 35Wọn yóò sọ wí pé, “Ilẹ̀ yìí tí ó ti wà ní ahoro tẹ́lẹ̀ ti dàbí ọgbà Edeni; àwọn ìlú tí ó wà ní wíwó lulẹ̀, ahoro tí a ti parun, ni àwa yóò mọdi sí tí yóò sì wà fún gbígbé ni ìsinsin yìí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.