Esekiẹli 35:9
Ezekiel 35:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò mú kí ó di ahoro títí láé, kò ní sí olùgbé ní ìlú rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.
Ezekiel 35:9 in English
Ezekiel 35:9 · Berean Standard Bible
I will make you a perpetual desolation, and your cities will not be inhabited. Then you will know that I am the LORD.
Context
7Èmi yóò mú kí òkè Seiri di ahoro; ọ̀fọ̀ gbogbo àwọn tí ó ń lọ tí ó ń bọ̀ ní èmi yóò gé kúrò lára rẹ. 8Èmi yóò fi àwọn tí a pa kún orí òkè rẹ, àwọn tí a fi idà pa yóò ṣubú ní orí òkè rẹ, àti ní àárín àwọn òkè rẹ. 9Èmi yóò mú kí ó di ahoro títí láé, kò ní sí olùgbé ní ìlú rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa. 10“ ‘Nítorí tí ìwọ sọ pé, “Àwọn orílẹ̀-èdè àti ilẹ̀ méjì wọ̀nyí yóò jẹ́ tiwa, àwa yóò sì gbà wọ́n ní ìní,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, Èmi Olúwa wà níbẹ̀, 11nítorí náà níwọ̀n ìgbà tí mo ti wà láààyè, ní Olúwa Olódùmarè wí, èmi yóò hùwà sí ọ ní ìbámu pẹ̀lú ìbínú àti owú tí o fihàn nínú ìkórìíra rẹ sí wọn, èmi yóò fi ara mi hàn ní àárín wọn, nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.