Native Bible

Ezekiel 35:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò mú kí òkè Seiri di ahoro; ọ̀fọ̀ gbogbo àwọn tí ó ń lọ tí ó ń bọ̀ ní èmi yóò gé kúrò lára rẹ.

Ezekiel 35:7 in English

Ezekiel 35:7 · Berean Standard Bible

I will make Mount Seir a desolate waste and will cut off from it those who come and go.

Context

5“ ‘Nítorí ìwọ dá ààbò bo ọ̀tẹ̀ àtayébáyé, tí ìwọ sì fi Israẹli lé idà lọ́wọ́, ní àsìkò ìdààmú wọn, ní àsìkò tí ìjìyà wọn dé góńgó, 6nítorí náà bi mo ti wà láààyè, ni Olúwa Olódùmarè wí, èmi yóò fi ọ kalẹ̀ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò sì lépa rẹ. Níwọ́n ìgbà tí ìwọ kò ti kórìíra ìtàjẹ̀ sílẹ̀, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò sì lépa rẹ. 7Èmi yóò mú kí òkè Seiri di ahoro; ọ̀fọ̀ gbogbo àwọn tí ó ń lọ tí ó ń bọ̀ ní èmi yóò gé kúrò lára rẹ. 8Èmi yóò fi àwọn tí a pa kún orí òkè rẹ, àwọn tí a fi idà pa yóò ṣubú ní orí òkè rẹ, àti ní àárín àwọn òkè rẹ. 9Èmi yóò mú kí ó di ahoro títí láé, kò ní sí olùgbé ní ìlú rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.