Esekiẹli 33:15
Ezekiel 33:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tí ó bá mu ògo padà, tí o sì da ohun tí o ti jí gbé padà, tí ó sì tẹ̀lé òfin tí ó ń fún ni ní ìyè, tí kò sì ṣe búburú, òun yóò yè dandan; òun kì yóò kú.
Ezekiel 33:15 in English
Ezekiel 33:15 · Berean Standard Bible
if he restores a pledge, makes restitution for what he has stolen, and walks in the statutes of life without practicing iniquity—then he will surely live; he will not die.
Context
13Bí mo bá sọ fún olódodo ènìyàn pé òun yóò yè, ṣùgbọ́n nígbà náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé òdodo rẹ̀ tí ó sì ṣe búburú, a kò ní rántí nǹkan kan nínú iṣẹ́ òdodo tí o ti ṣe sẹ́yìn; òun yóò kú nítorí búburú tí ó ṣe. 14Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé, ‘Ìwọ yóò kú dandan,’ ṣùgbọ́n tí ó bá yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ti o sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí o yẹ. 15Tí ó bá mu ògo padà, tí o sì da ohun tí o ti jí gbé padà, tí ó sì tẹ̀lé òfin tí ó ń fún ni ní ìyè, tí kò sì ṣe búburú, òun yóò yè dandan; òun kì yóò kú. 16A kò ní rántí ọ̀kan nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá. Ó ti ṣe èyí tí ó tọ àti èyí tí o yẹ; òun yóò sì yè dájúdájú. 17“Síbẹ̀ àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ sọ pé, ‘Ọ̀nà Olúwa kò tọ́.’ Ṣùgbọ́n ọ̀nà tí àwọn ní ó tọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.