Esekiẹli 32:27
Ezekiel 32:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn kì yóò sì dùbúlẹ̀ ti àwọn tí ó ṣubú nínú àwọn aláìkọlà, tí wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun wọn, wọ́n tí fi idà wọn rọ orí wọn. Ṣùgbọ́n àìṣedéédéé wọn yóò wà ní orí egungun wọn—bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ ẹ̀rù àwọn alágbára ní ilẹ̀ alààyè.
Ezekiel 32:27 in English
Ezekiel 32:27 · Berean Standard Bible
They do not lie down with the fallen warriors of old,* who went down to Sheol with their weapons of war, whose swords were placed under their heads, whose shields * rested on their bones, although the terror of the mighty was once in the land of the living.
Context
25A ṣe ibùsùn fún un láàrín àwọn tí a pa, pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀ tí ó yí isà òkú ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, tí a fi idà pa. Nítorí pé a tan ẹ̀rù wọn ká ilẹ̀ alààyè, wọn ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò; a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a pa. 26“Meṣeki àti Tubali wà níbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ogun wọn yí isà òkú wọn ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, wọ́n fi idà pa wọ́n nítorí ẹ̀rù tiwọn tàn ká ilẹ̀ alààyè. 27Wọn kì yóò sì dùbúlẹ̀ ti àwọn tí ó ṣubú nínú àwọn aláìkọlà, tí wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun wọn, wọ́n tí fi idà wọn rọ orí wọn. Ṣùgbọ́n àìṣedéédéé wọn yóò wà ní orí egungun wọn—bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ ẹ̀rù àwọn alágbára ní ilẹ̀ alààyè. 28“Ìwọ náà, Farao, ní yóò ṣẹ, ti yóò dùbúlẹ̀ láàrín aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. 29“Edomu wà níbẹ̀, àwọn ọba rẹ̀ àti gbogbo ọmọbìnrin ọba; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní agbára, a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. Wọn dùbúlẹ̀ pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn ti o lọ sínú kòtò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.