Native Bible

Ezekiel 32:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Meṣeki àti Tubali wà níbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ogun wọn yí isà òkú wọn ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, wọ́n fi idà pa wọ́n nítorí ẹ̀rù tiwọn tàn ká ilẹ̀ alààyè.

Ezekiel 32:26 in English

Ezekiel 32:26 · Berean Standard Bible

Meshech and Tubal are there with all their multitudes, with their graves all around them. All of them are uncircumcised, slain by the sword, because they spread their terror in the land of the living.

Context

24“Elamu wà níbẹ̀, o yí isà òkú rẹ̀ ká pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀. Gbogbo wọn ni a pa, àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè lọ sí ìsàlẹ̀ láìkọlà sí abẹ́ ilẹ̀. Wọ́n gba ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò. 25A ṣe ibùsùn fún un láàrín àwọn tí a pa, pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀ tí ó yí isà òkú ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, tí a fi idà pa. Nítorí pé a tan ẹ̀rù wọn ká ilẹ̀ alààyè, wọn ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò; a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a pa. 26“Meṣeki àti Tubali wà níbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ogun wọn yí isà òkú wọn ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, wọ́n fi idà pa wọ́n nítorí ẹ̀rù tiwọn tàn ká ilẹ̀ alààyè. 27Wọn kì yóò sì dùbúlẹ̀ ti àwọn tí ó ṣubú nínú àwọn aláìkọlà, tí wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun wọn, wọ́n tí fi idà wọn rọ orí wọn. Ṣùgbọ́n àìṣedéédéé wọn yóò wà ní orí egungun wọn—bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ ẹ̀rù àwọn alágbára ní ilẹ̀ alààyè. 28“Ìwọ náà, Farao, ní yóò ṣẹ, ti yóò dùbúlẹ̀ láàrín aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.