Esekiẹli 32:22
Ezekiel 32:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Asiria wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo jagunjagun rẹ̀; àwọn isà òkú àwọn tí a ti pa sì yí i ká, gbogbo àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú.
Ezekiel 32:22 in English
Ezekiel 32:22 · Berean Standard Bible
Assyria is there with her whole company; her graves are all around her. All of them are slain, fallen by the sword.
Context
20Wọn yóò ṣubú láàrín àwọn tí a fi idà pa. A fa idà yọ; jẹ́ kí a wọ́ Ejibiti kúrò pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀. 21Láti inú isà òkú alágbára tí í ṣe aṣáájú yóò sọ nípa Ejibiti àti àwọn àlejò rẹ̀, ‘Wọn ti wá sí ìsàlẹ̀, wọn sì sùn pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.’ 22“Asiria wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo jagunjagun rẹ̀; àwọn isà òkú àwọn tí a ti pa sì yí i ká, gbogbo àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú. 23Isà òkú wọn wà ní ibi tí ó jinlẹ̀ gan an nínú kòtò. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè ní a pa, tí ó ti ipa idà ṣubú. 24“Elamu wà níbẹ̀, o yí isà òkú rẹ̀ ká pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀. Gbogbo wọn ni a pa, àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè lọ sí ìsàlẹ̀ láìkọlà sí abẹ́ ilẹ̀. Wọ́n gba ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.