Esekiẹli 3:1
Ezekiel 3:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Síwájú sí i, ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ohun tí ó wà níwájú rẹ, jẹ ìwé kíká yìí; kí o sì lọ fi bá ilé Israẹli sọ̀rọ̀.”
Ezekiel 3:1 in English
Ezekiel 3:1 · Berean Standard Bible
“Son of man,” He said to me, “eat what you find here. Eat this scroll, then go and speak to the house of Israel.”
Context
1Síwájú sí i, ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ohun tí ó wà níwájú rẹ, jẹ ìwé kíká yìí; kí o sì lọ fi bá ilé Israẹli sọ̀rọ̀.” 2Mo sì ya ẹnu mi, ó sì mú mi jẹ ìwé kíká náà. 3Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ìwé kíká tí mo fún ọ yìí, fi bọ́ inú àti ikùn rẹ.” Nígbà náà ni mo jẹ ẹ́, dídùn rẹ̀ dàbí oyin ní ẹnu mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.