Esekiẹli 27:25
Ezekiel 27:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Àwọn ọkọ̀ Tarṣiṣi ní èrò ní ọjà rẹ a ti mú ọ gbilẹ̀ a sì ti ṣe ọ́ lógo ní àárín gbùngbùn Òkun.
Ezekiel 27:25 in English
Ezekiel 27:25 · Berean Standard Bible
The ships of Tarshish * carried your merchandise. And you were filled with heavy cargo in the heart of the sea.
Context
23“ ‘Harani àti Kanneh àti Edeni, àwọn oníṣòwò Ṣeba, Asiria àti Kilmadi, ni àwọn oníṣòwò rẹ. 24Wọ̀nyí ní oníbàárà rẹ ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oníṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ olówó iyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi kedari ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ. 25“ ‘Àwọn ọkọ̀ Tarṣiṣi ní èrò
ní ọjà rẹ
a ti mú ọ gbilẹ̀
a sì ti ṣe ọ́ lógo
ní àárín gbùngbùn Òkun. 26Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọ
wá sínú omi ńlá.
Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́
ní àárín gbùngbùn Òkun. 27Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ,
àwọn ìṣúra rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ.
Àwọn oníbàárà rẹ àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹ,
àti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹ
tí ó wà ní àárín rẹ
yóò rì sínú àárín gbùngbùn Òkun
ní ọjọ́ ìparun rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.