Esekiẹli 26:4
Ezekiel 26:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn yóò wó odi tire lulẹ̀, wọn yóò sì wo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀, Èmi yóò sì ha erùpẹ̀ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orí àpáta.
Ezekiel 26:4 in English
Ezekiel 26:4 · Berean Standard Bible
They will destroy the walls of Tyre and demolish her towers. I will scrape the soil from her and make her a bare rock.
Context
2“Ọmọ ènìyàn, nítorí pé Tire sọ nípa Jerusalẹmu pé, ‘Háà! A fọ́ èyí tí í ṣe bodè àwọn orílẹ̀-èdè, a yí i padà sí mi, èmi yóò di kíkún, òun yóò sì di ahoro,’ 3nítorí náà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, kíyèsi i, èmí dojúkọ ọ́ ìwọ tire, Èmi yóò sì jẹ́ kí Orílẹ̀-èdè púpọ̀ dìde sí ọ, gẹ́gẹ́ bí Òkun tí ru sókè. 4Wọn yóò wó odi tire lulẹ̀, wọn yóò sì wo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀, Èmi yóò sì ha erùpẹ̀ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orí àpáta. 5Yóò sì jẹ́ ibi nína àwọ̀n tí wọn fi ń pẹja sí láàrín Òkun, ní Olúwa Olódùmarè wí. Yóò di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè. 6Ìlú tí ó tẹ̀dó sí, ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó fi idà sọ ọ́ di ahoro. Nígbà náà ní wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.