Native Bible

Ezekiel 26:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí Tire: Ǹjẹ́ àwọn erékùṣù kì yóò ha wárìrì nípa ìṣubú rẹ, nígbà tí ìkórìíra ìpalára àti rírẹ́ni lọ́run bá ń ṣẹlẹ̀ ní inú rẹ?

Ezekiel 26:15 in English

Ezekiel 26:15 · Berean Standard Bible

This is what the Lord GOD says to Tyre: ‘Will not the coastlands quake at the sound of your downfall, when the wounded groan at the slaughter in your midst?

Context

13Èmi yóò sì mú ariwo orin rẹ̀ dákẹ́ àti ìró dùùrù orin rẹ̀ ni a kì yóò gbọ́ mọ́. 14Èmi yóò sọ ọ di àpáta lásán, ìwọ yóò sì di ibi tí a ń sá àwọ̀n ẹja sí. A kì yóò sì tún ọ mọ nítorí Èmi Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ ní Olúwa Olódùmarè wí. 15“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí Tire: Ǹjẹ́ àwọn erékùṣù kì yóò ha wárìrì nípa ìṣubú rẹ, nígbà tí ìkórìíra ìpalára àti rírẹ́ni lọ́run bá ń ṣẹlẹ̀ ní inú rẹ? 16Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ-aládé etí Òkun yóò sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn yóò sì pa àwọn aṣọ ìgúnwà wọn da, tì wọn yóò sì bọ́ àwọn aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ kúrò. Ẹ̀rù yóò bò wọ́n, wọn yóò sì jókòó lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀, wọn yóò sì máa wárìrì ní gbogbo ìgbà, ẹnu yóò sì yà wọ́n sí ọ́. 17Nígbà náà wọn yóò gbóhùn ẹkún sókè nítorí rẹ, wọn yóò sì wí fún ọ pé: “ ‘Báwo ni a ṣe pa ọ́ run, ìwọ ìlú olókìkí ìwọ tí àwọn èrò okun ti gbé inú rẹ̀! Ìwọ jẹ alágbára lórí okun gbogbo òun àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; ìwọ gbé ẹ̀rù rẹ lórí gbogbo olùgbé ibẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.