Native Bible

Ezekiel 24:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ní ọjọ́ náà ẹni tí ó bá sálà yóò tọ̀ ọ́ wá láti sọ ìròyìn náà fún ọ.

Ezekiel 24:26 in English

Ezekiel 24:26 · Berean Standard Bible

on that day a fugitive will come and tell you the news.

Context

24Esekiẹli yóò jẹ àmì fún un yín; ẹ̀yin yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe. Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.’ 25“Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ, Ọmọ ènìyàn, kì yóò ha jẹ́ pé, ní ọjọ́ náà, nígbà ti mo bá gba agbára wọn, ayọ̀ wọn àti ògo wọn, ìfẹ́ ojú wọn, ohun tí wọn gbé ọkàn wọn lé, àti àwọn ọmọ ọkùnrin wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ obìnrin wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn, 26ní ọjọ́ náà ẹni tí ó bá sálà yóò tọ̀ ọ́ wá láti sọ ìròyìn náà fún ọ. 27Ní ọjọ́ náà ẹnu rẹ yóò sì ṣí; ìwọ yóò sọ̀rọ̀, ìwọ kì yóò sì yadi mọ́. Báyìí ìwọ yóò jẹ́ àmì fún wọn; wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ní Olúwa.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.