Native Bible

Ezekiel 23:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bákan náà ni wọ́n ti ṣe èyí náà sí mi. Ní àkókò kan náà wọn ba ibi mímọ́ mi jẹ́, wọ́n sì lo ọjọ́ ìsinmi mi ní àìmọ́.

Ezekiel 23:38 in English

Ezekiel 23:38 · Berean Standard Bible

They have also done this to Me: On that very same day, they defiled My sanctuary and profaned My Sabbaths.

Context

36Olúwa sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, ń jẹ́ ìwọ yóò ṣe ìdájọ́ Ohola àti Oholiba? Nítorí náà dojúkọ wọn nípa ìkórìíra tí wọn ń ṣe, 37nítorí wọn ti dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn. Wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà pẹ̀lú àwọn òrìṣà wọn; kódà wọ́n fi àwọn ọmọ wọn tí wọn bí fún ni ṣe ìrúbọ, gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ fún wọn. 38Bákan náà ni wọ́n ti ṣe èyí náà sí mi. Ní àkókò kan náà wọn ba ibi mímọ́ mi jẹ́, wọ́n sì lo ọjọ́ ìsinmi mi ní àìmọ́. 39Ní ọjọ́ náà gan an wọ́n fi àwọn ọmọ wọn rú ẹbọ sí àwọn òrìṣà, wọn wọ ibi mímọ́ mi lọ wọn sì lò ó ní ìlòkulò. Ìyẹn ní wọn ṣe ní ilé mi. 40“Wọn tilẹ̀ rán oníṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn, nígbà tí wọ́n dé, ìwọ wẹ ara rẹ fún wọn, ìwọ kún ojú rẹ, ìwọ sì fi ọ̀ṣọ́ iyebíye sára.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.