Native Bible

Ezekiel 22:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nínú rẹ ni àwọn ayannijẹ ènìyàn pinnu láti tàjẹ̀ sílẹ̀; nínú rẹ ní àwọn tí ó ń jẹun ní orí òkè ojúbọ òrìṣà, wọn sì hùwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.

Ezekiel 22:9 in English

Ezekiel 22:9 · Berean Standard Bible

Among you are slanderous men bent on bloodshed; within you are those who eat on the mountain shrines and commit acts of indecency.

Context

7Nínú rẹ wọn ti hùwà sí baba àti ìyá pẹ̀lú ìfojú tínrín; nínú rẹ wọn ti ni àwọn àlejò lára, wọn sì hùwàkiwà sí aláìní baba àti opó. 8Ìwọ tí kọ àwọn ohun mímọ́ mi sílẹ̀, ìwọ sì ti lo ọjọ́ ìsinmi mi ní ìlòkulò. 9Nínú rẹ ni àwọn ayannijẹ ènìyàn pinnu láti tàjẹ̀ sílẹ̀; nínú rẹ ní àwọn tí ó ń jẹun ní orí òkè ojúbọ òrìṣà, wọn sì hùwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. 10Nínú rẹ ní àwọn ti kò bu ọlá fún àwọn àkéte baba wọn; nínú rẹ ni àwọn tí o ń bá àwọn obìnrin lò nígbà tí wọ́n ń ṣe àkókò lọ́wọ́, ní àsìkò tí a ka wọn sì aláìmọ́. 11Nínú rẹ ọkùnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ìríra pẹ̀lú aya aládùúgbò rẹ̀, òmíràn bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ jẹ́, òmíràn sì bá arábìnrin rẹ̀ lòpọ̀ èyí tí í ṣe ọbàkan rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.