Native Bible

Ezekiel 22:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nínú rẹ ní àwọn ti kò bu ọlá fún àwọn àkéte baba wọn; nínú rẹ ni àwọn tí o ń bá àwọn obìnrin lò nígbà tí wọ́n ń ṣe àkókò lọ́wọ́, ní àsìkò tí a ka wọn sì aláìmọ́.

Ezekiel 22:10 in English

Ezekiel 22:10 · Berean Standard Bible

In you they have uncovered the nakedness of their fathers; in you they violate women during their menstrual impurity.

Context

8Ìwọ tí kọ àwọn ohun mímọ́ mi sílẹ̀, ìwọ sì ti lo ọjọ́ ìsinmi mi ní ìlòkulò. 9Nínú rẹ ni àwọn ayannijẹ ènìyàn pinnu láti tàjẹ̀ sílẹ̀; nínú rẹ ní àwọn tí ó ń jẹun ní orí òkè ojúbọ òrìṣà, wọn sì hùwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. 10Nínú rẹ ní àwọn ti kò bu ọlá fún àwọn àkéte baba wọn; nínú rẹ ni àwọn tí o ń bá àwọn obìnrin lò nígbà tí wọ́n ń ṣe àkókò lọ́wọ́, ní àsìkò tí a ka wọn sì aláìmọ́. 11Nínú rẹ ọkùnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ìríra pẹ̀lú aya aládùúgbò rẹ̀, òmíràn bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ jẹ́, òmíràn sì bá arábìnrin rẹ̀ lòpọ̀ èyí tí í ṣe ọbàkan rẹ̀. 12Nínú rẹ àwọn ènìyàn gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀; ìwọ gba èlé ìlọ́po láti mú aláìṣòótọ́ jèrè láti ara aládùúgbò rẹ nípa ìrẹ́jẹ. Ìwọ sì ti gbàgbé èmi; ni Olúwa Olódùmarè wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.