Esekiẹli 22:23
Ezekiel 22:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́ẹ̀kan sí i ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé,
Ezekiel 22:23 in English
Ezekiel 22:23 · Berean Standard Bible
And the word of the LORD came to me, saying,
Context
21Èmi yóò kó yín jọ, èmi o sì fín iná ìbínú mi si yin lára, ẹ o si di yíyọ́ láàrín rẹ̀. 22Bí a ti ń yọ́ fàdákà nínú iná ìléru bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ìwọ yóò ṣe yọ́ nínú rẹ̀, ìwọ yóò sì mọ̀ wí pé, Èmi Olúwa ti tú ìbínú mi sórí rẹ.’ ” 23Lẹ́ẹ̀kan sí i ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé, 24“Ọmọ ènìyàn, sọ fún ilẹ̀ náà, ‘Ìwọ ní ilẹ̀ tí kò gbá mọ́, ti kò sì rọ òjò tàbí ìrì ní àkókò ìbínú.’ 25Ìdìtẹ̀ sì wà láàrín àwọn ọmọ-aládé inú rẹ̀, tó dàbí bíbú kìnnìún tó ń fà ẹran ya, wọ́n ń ba àwọn ènìyàn jẹ́, wọ́n ń kó ìṣúra àti àwọn ohun iyebíye wọ́n sì ń sọ púpọ̀ di opó nínú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.