Native Bible

Ezekiel 21:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ọmọ ènìyàn la ọ̀nà méjì fún idà ọba Babeli láti gbà, kí méjèèjì bẹ̀rẹ̀ láti ìlú kan náà. Ṣe àmì sí ìkóríta ọ̀nà tí ó lọ sí ìlú náà.

Ezekiel 21:19 in English

Ezekiel 21:19 · Berean Standard Bible

“Now you, son of man, mark out two roads for the sword of the king of Babylon to take, both starting from the same land. And make a signpost where the road branches off to each city.

Context

17Èmi gan an yóò pàtẹ́wọ́ ìbínú mi yóò sì rẹlẹ̀. Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀.” 18Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mi wá: 19“Ọmọ ènìyàn la ọ̀nà méjì fún idà ọba Babeli láti gbà, kí méjèèjì bẹ̀rẹ̀ láti ìlú kan náà. Ṣe àmì sí ìkóríta ọ̀nà tí ó lọ sí ìlú náà. 20La ọ̀nà kan fún idà láti wá kọlu Rabba ti àwọn ará Ammoni kí òmíràn kọlu Juda, kí ó sì kọlu Jerusalẹmu ìlú olódi. 21Nítorí ọba Babeli yóò dúró ni ìyànà ní ojú ọ̀nà, ní ìkóríta, láti máa lo àfọ̀ṣẹ. Yóò fi ọfà di ìbò, yóò béèrè lọ́wọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀, òun yóò ṣe àyẹ̀wò ẹ̀dọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.