Esekiẹli 18:11
Ezekiel 18:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
(tí kò sì ṣe ọ̀kan nínú gbogbo iṣẹ́ wọ̀n-ọn-nì): “Ó ń jẹun lójúbọ lórí òkè gíga, tí ó sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́.
Ezekiel 18:11 in English
Ezekiel 18:11 · Berean Standard Bible
though the father has done none of them: Indeed, the son eats at the mountain and defiles his neighbor’s wife.
Context
9Tí ó ń tẹ̀lé àṣẹ mi,
tí ó sì ń pa òfin mi mọ́ lóòtítọ́ àti lódodo.
Ó jẹ́ olódodo,
yóò yè nítòótọ́,
ní Olúwa Olódùmarè wí. 10“Bí ó bá bi ọmọkùnrin, oníwà ipá, tó ń jalè, tó tún ń pànìyàn, tó sì ń ṣe gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí sí arákùnrin rẹ̀ 11(tí kò sì ṣe ọ̀kan nínú gbogbo iṣẹ́ wọ̀n-ọn-nì):
“Ó ń jẹun lójúbọ lórí òkè gíga,
tí ó sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́. 12Ó ni àwọn tálákà àti aláìní lára,
ó ń fipá jalè, kì í dá padà gẹ́gẹ́ bí ìlérí,
o gbójú sókè sí òrìṣà,
ó sì ń ṣe ohun ìríra. 13Ó ń fi owó ya ni pẹ̀lú èlé, ó sì tún ń gba èlé tó pọ̀jù.
Ǹjẹ́ irú ọkùnrin yìí wa le è yè bí? Òun kì yóò wá láààyè! Nítorí pé òun ti ṣe àwọn ohun ìríra yìí, kíkú ni yóò kú, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wá lórí rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.