Native Bible

Ezekiel 17:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mi wá pé:

Ezekiel 17:11 in English

Ezekiel 17:11 · Berean Standard Bible

Then the word of the LORD came to me, saying,

Context

9“Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nìyí, yóò wá gbilẹ̀ bí? A kò wá ní i wú gbòǹgbò rẹ̀, ki a si gé èso rẹ̀ kúrò kí ó bá à le rọ? Gbogbo ewé rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ni yóò rẹ̀. Kò sì nígbà agbára tàbí ènìyàn púpọ̀ láti fà gbòǹgbò rẹ̀ tu. 10Bí a tilẹ̀ tún un gbìn, yóò wa gbilẹ̀ bí? Kò wá ní i rọ pátápátá nígbà ti afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn bá kọlù ú. Gbogbo ewé rẹ̀ yóò rẹ̀ lórí ilẹ̀ tó ti dàgbà?’ ” 11Nígbà náà, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mi wá pé: 12“Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé yìí, ‘Ǹjẹ́ ẹ mọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?’ Sọ fún wọn: ‘Ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu, ó sì kó ọba àti àwọn ìjòyè ọmọ-aládé ibẹ̀ lọ sí Babeli lọ́dọ̀ rẹ̀. 13Lẹ́yìn èyí, ó bá ọ̀kan nínú ọmọ ọba dá májẹ̀mú, ó mú un ìbúra, ó tún kó àwọn alágbára ilẹ̀ náà lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.