Native Bible

Ezekiel 16:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní gbogbo ìkóríta ni ìwọ lọ kọ ojúbọ gíga sí, tí ìwọ sọ ẹwà rẹ di ìkórìíra, ìwọ sọ àgbèrè rẹ di púpọ̀ nípa fífi ara rẹ sílẹ̀ fún gbogbo ẹni tó ń kọjá lọ.

Ezekiel 16:25 in English

Ezekiel 16:25 · Berean Standard Bible

At the head of every street you built your lofty shrines and degraded your beauty. With increasing promiscuity, you spread your legs to all who passed by.

Context

23“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, ‘Ègbé! Ègbé ni fún ọ. Lẹ́yìn gbogbo ìwà búburú rẹ, 24ìwọ kọ́lé amọ̀ fún ara rẹ, ìwọ sì kọ́ ojúbọ gíga sí gbogbo òpin ojú pópó. 25Ní gbogbo ìkóríta ni ìwọ lọ kọ ojúbọ gíga sí, tí ìwọ sọ ẹwà rẹ di ìkórìíra, ìwọ sọ àgbèrè rẹ di púpọ̀ nípa fífi ara rẹ sílẹ̀ fún gbogbo ẹni tó ń kọjá lọ. 26Ìwọ ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú ará Ejibiti tí í ṣe aládùúgbò rẹ láti mú mi bínú ìwọ sì ti sọ àgbèrè rẹ di púpọ̀. 27Nítorí náà ni mo fi na ọwọ́ mi lé ọ lórí, mo sì ti bu oúnjẹ rẹ̀ kù; èmi yóò sì mú ìfẹ́ àwọn to kórìíra rẹ ṣẹ́ lé ọ lórí, àwọn ọmọbìnrin Filistini ti ìwàkiwà rẹ tì lójú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.