Esekiẹli 14:20
Ezekiel 14:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
bó tilẹ̀ jẹ́ pé Noa, Daniẹli àti Jobu wà nínú rẹ, bí mo ti wà láààyè ni Olúwa Olódùmarè wí, wọn kò le gba ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin wọn lá. Ara wọn nìkan ni ìwà òdodo wọn lè gbàlà.
Ezekiel 14:20 in English
Ezekiel 14:20 · Berean Standard Bible
then as surely as I live, declares the Lord GOD, even if Noah, Daniel, and Job were in it, they could not deliver their own sons or daughters. Their righteousness could deliver only themselves.
Context
18Bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí tilẹ̀ wà nínú rẹ̀, Olúwa Olódùmarè wí pé, bí mo ti wà, wọn ki yóò gba ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin là, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn nìkan ni a ó gbàlà. 19“Tàbí bí mo rán àjàkálẹ̀-ààrùn si ilẹ̀ náà, ti mo si da ìrunú mi lé e lórí pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, láti gé ènìyàn àti ẹranko kúrò nínú rẹ̀, 20bó tilẹ̀ jẹ́ pé Noa, Daniẹli àti Jobu wà nínú rẹ, bí mo ti wà láààyè ni Olúwa Olódùmarè wí, wọn kò le gba ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin wọn lá. Ara wọn nìkan ni ìwà òdodo wọn lè gbàlà. 21“Nítorí báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, báwo ni yóò ti burú tó nígbà tí mo bá rán ìdájọ́ kíkan mi mẹ́rin sórí Jerusalẹmu, èyí ni idà àti ìyàn, ẹranko búburú àti àjàkálẹ̀-ààrùn láti pa àwọn ènìyàn àti ẹranko inú rẹ̀! 22Síbẹ̀, yóò ṣẹ́kù àwọn díẹ̀, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí a ó kó jáde nínú rẹ̀. Wọn yóò wá bá yin, ẹ̀yin yóò rí ìwà àti ìṣe wọn, nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rí ìtùnú nípa àjálù tí mo mú wá sórí Jerusalẹmu—àní gbogbo àjálù ní mo ti mú wá sórí rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.