Native Bible

Ezekiel 13:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin kò ha ti rí ìran asán, ẹ̀yin kò ha ti fọ àfọ̀ṣẹ èké, nígbà tí ẹ̀yin sọ pé, “Olúwa wí,” bẹ́ẹ̀ sì ni Èmi kò sọ̀rọ̀?

Ezekiel 13:7 in English

Ezekiel 13:7 · Berean Standard Bible

Haven’t you seen a false vision and spoken a lying divination when you proclaim, ‘Thus declares the LORD,’ even though I have not spoken?

Context

5Ẹ̀yin kò gòkè láti mọ odi tí ó ya ní ilé Israẹli kí wọ́n ba lè dúró gbọin ní ojú ogun ní ọjọ́ Olúwa. 6Ìran àti àfọ̀ṣẹ wọn jẹ́ èké. Wọ́n wí pé, “Olúwa wí,” nígbà tí Olúwa kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n fẹ́ kí Olúwa mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ. 7Ẹ̀yin kò ha ti rí ìran asán, ẹ̀yin kò ha ti fọ àfọ̀ṣẹ èké, nígbà tí ẹ̀yin sọ pé, “Olúwa wí,” bẹ́ẹ̀ sì ni Èmi kò sọ̀rọ̀? 8“ ‘Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, Nítorí ọ̀rọ̀ asán àti ìran èké yín, mo lòdì sí yín: ni Olúwa Olódùmarè wí. 9Ọwọ́ mi yóò sì wà lórí àwọn wòlíì tó ń ríran asán, tó sì ń sọ àfọ̀ṣẹ èké. Wọn kò ní sí nínú ìjọ àwọn ènìyàn mi, a ó sì yọ orúkọ wọn kúrò nínú àkọsílẹ̀ ilé Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì ní wọ ilẹ̀ Israẹli mọ́. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa Olódùmarè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.