Native Bible

Ezekiel 13:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Israẹli àwọn wòlíì rẹ dàbí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ nínú pápá.

Ezekiel 13:4 in English

Ezekiel 13:4 · Berean Standard Bible

Your prophets, O Israel, are like foxes among the ruins.

Context

2“Ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ lòdì sí àwọn wòlíì Israẹli tó ń sọtẹ́lẹ̀, kí o sì sọ fún àwọn tí ń sọtẹ́lẹ̀ láti inú èrò ọkàn wọn, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa! 3Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ègbé ni fún àwọn aṣiwèrè wòlíì tó ń tẹ̀lé ẹ̀mí ara wọn tí wọn kò sì rí nǹkan kan! 4Israẹli àwọn wòlíì rẹ dàbí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ nínú pápá. 5Ẹ̀yin kò gòkè láti mọ odi tí ó ya ní ilé Israẹli kí wọ́n ba lè dúró gbọin ní ojú ogun ní ọjọ́ Olúwa. 6Ìran àti àfọ̀ṣẹ wọn jẹ́ èké. Wọ́n wí pé, “Olúwa wí,” nígbà tí Olúwa kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n fẹ́ kí Olúwa mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.