Esekiẹli 12:5
Ezekiel 12:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dá ògiri lu ní ojú wọn, kí ìwọ sì gba ibẹ̀ kó ẹrù rẹ jáde.
Ezekiel 12:5 in English
Ezekiel 12:5 · Berean Standard Bible
As they watch, dig through the wall and carry your belongings out through it.
Context
3“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, palẹ̀ ẹrù rẹ mọ́ láti lọ sí ìgbèkùn, ní ọ̀sán gangan ní ojú wọn, kúrò láti ibi tí ìwọ wà lọ sí ibòmíràn. Bóyá bí wọ́n bá rí ọ, wọn yóò sì ronú bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n. 4Di ẹrù ìgbèkùn rẹ lójú wọn ní ọ̀sán án gangan, nígbà tí ó bá sì di alẹ́, ní ojú wọn, máa lọ sí ìgbèkùn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó lọ ìgbèkùn ṣe máa ń ṣe. 5Dá ògiri lu ní ojú wọn, kí ìwọ sì gba ibẹ̀ kó ẹrù rẹ jáde. 6Gbé ẹrù rẹ lé èjìká ní ojú wọn, bo ojú rẹ, kí ìwọ má ba à rí ilẹ̀, sì ru ẹrù rẹ lọ ní alẹ́ nítorí pé mo fi ọ́ ṣe àmì fún ilé Israẹli.” 7Mo ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún mi. Mo kó ẹrù mi jáde ní ọ̀sán án láti lọ fun ìgbèkùn. Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, mo dá ògiri lu pẹ̀lú ọwọ́ mi. Mo sì gbe ẹrù mi lé èjìká nínú òkùnkùn ní ojú wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.