Esekiẹli 12:22
Ezekiel 12:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ọmọ ènìyàn, irú òwe wo ni ẹ pa nílẹ̀ Israẹli pé: ‘A fa ọjọ́ gùn, gbogbo ìran di asán’?
Ezekiel 12:22 in English
Ezekiel 12:22 · Berean Standard Bible
“Son of man, what is this proverb that you have in the land of Israel: ‘The days go by, and every vision fails’?
Context
20Ìlú tó jẹ́ ibùgbé ènìyàn tẹ́lẹ̀ yóò di òfo, ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro. Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ” 21Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé: 22“Ọmọ ènìyàn, irú òwe wo ni ẹ pa nílẹ̀ Israẹli pé: ‘A fa ọjọ́ gùn, gbogbo ìran di asán’? 23Nítorí náà wí fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, Èmi yóò fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní ipa mọ́ ní Israẹli.’ Sọ fún wọn, ‘Ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí nígbà tí gbogbo ìran àti ìsọtẹ́lẹ̀ yóò sì wá sí ìmúṣẹ. 24Nítorí kò ní sí ìran asán tàbí àfọ̀ṣẹ tí ó ń pọ́n ni mọ́ ní àárín ilé Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.