Esekiẹli 1:4
Ezekiel 1:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo wò, mo sì rí ìjì tó ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá ìkùùkuu tó nípọn pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná ti n bù yẹ̀rì pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rokoṣo tó yí i ká. Àárín iná náà rí bí ìgbà tí irin bá ń bẹ nínú iná,
Ezekiel 1:4 in English
Ezekiel 1:4 · Berean Standard Bible
I looked and saw a whirlwind coming from the north, a great cloud with fire flashing back and forth and brilliant light all around it. In the center of the fire was a gleam like amber,*
Context
2Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù—tí ó jẹ́ ọdún karùn-ún ìgbèkùn ọba Jehoiakini— 3ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ àlùfáà Esekiẹli, ọmọ Busii wá, létí odò Kebari ni ilẹ̀ àwọn ará Babeli. Níbẹ̀ ni ọwọ́ Olúwa ti wà lára rẹ̀. 4Mo wò, mo sì rí ìjì tó ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá ìkùùkuu tó nípọn pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná ti n bù yẹ̀rì pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rokoṣo tó yí i ká. Àárín iná náà rí bí ìgbà tí irin bá ń bẹ nínú iná, 5àti láàrín iná náà ni ohun tó dàbí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin wà. Ìrísí wọn jẹ́ ti ènìyàn, 6ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.