Esekiẹli 1:16
Ezekiel 1:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àpèjúwe àti ìrísí àwọn kẹ̀kẹ́ náà nìyìí: kẹ̀kẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rí bákan náà, wọ́n sì ń tàn yinrin yinrin bí i kirisoleti, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kẹ̀kẹ́ yìí rí bí i ìgbà tí a fi kẹ̀kẹ́ bọ kẹ̀kẹ́ nínú.
Ezekiel 1:16 in English
Ezekiel 1:16 · Berean Standard Bible
The workmanship of the wheels looked like the gleam of beryl, and all four had the same likeness. Their workmanship looked like a wheel within a wheel.
Context
14Àwọn ẹ̀dá alààyè yìí sì ń sáré lọ sókè lọ sódò bí i ìtànṣán àrá. 15Bí mo ti ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè yìí, mo rí kẹ̀kẹ́ ní ilẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí pẹ̀lú ojú rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. 16Àpèjúwe àti ìrísí àwọn kẹ̀kẹ́ náà nìyìí: kẹ̀kẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rí bákan náà, wọ́n sì ń tàn yinrin yinrin bí i kirisoleti, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kẹ̀kẹ́ yìí rí bí i ìgbà tí a fi kẹ̀kẹ́ bọ kẹ̀kẹ́ nínú. 17Àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń yí bí wọ́n ti ń yí, wọ́n ń lọ tààrà sí ibi tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè kọjú sí, kẹ̀kẹ́ wọn kò sì yapa bí àwọn ẹ̀dá náà ti n lọ. 18Àwọn ríìmù wọ́n ga, wọ́n sì ba ni lẹ́rù, àwọn ríìmù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì jẹ́ kìkìdá ojú yíká.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.