Eksodu 8:28
Exodus 8:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Farao wí pé, “Èmi yóò jẹ́ ki ẹ lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín nínú aginjù, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rìn jìnnà jù. Ẹ gbàdúrà fún mi.”
Exodus 8:28 in English
Exodus 8:28 · Berean Standard Bible
Pharaoh answered, “I will let you go and sacrifice to the LORD your God in the wilderness, but you must not go very far. Now pray for me.”
Context
26Ṣùgbọ́n Mose sọ pé, “Èyí ló tọ́, ẹbọ tí a ó rú sí Olúwa Ọlọ́run wa yóò jẹ́ ohun ìríra sí àwọn ará ilẹ̀ Ejibiti. Bí a bá ṣe ìrúbọ ti yóò jẹ́ ìríra ni ojú wọn ṣé wọn, ó ní sọ òkúta lù wá? 27A gbọdọ̀ lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú aginjù láti rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wa.” 28Nígbà náà ni Farao wí pé, “Èmi yóò jẹ́ ki ẹ lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín nínú aginjù, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rìn jìnnà jù. Ẹ gbàdúrà fún mi.” 29Mose dáhùn ó wí pé, “Bí èmi bá ti kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa, àwọn ọ̀wọ́ eṣinṣin yóò fi Farao, àwọn ìjòyè rẹ, àti àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀ ní ọ̀la ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ìdánilójú wa pé Farao kò tún ni lo ẹ̀tàn láti má jẹ́ kí àwọn ènìyàn kí ó lọ rú ẹbọ sí Olúwa.” 30Nígbà náà ni Mose kúrò ni ọ̀dọ̀ Farao, ó sì gbàdúrà sí Olúwa;
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.