Native Bible

Exodus 8:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A gbọdọ̀ lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú aginjù láti rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wa.”

Exodus 8:27 in English

Exodus 8:27 · Berean Standard Bible

We must make a three-day journey into the wilderness and sacrifice to the LORD our God as He commands us.”

Context

25Nígbà náà ni Farao ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ kí ẹ sì rú ẹbọ sí Ọlọ́run yín ní ilẹ̀ yìí.” 26Ṣùgbọ́n Mose sọ pé, “Èyí ló tọ́, ẹbọ tí a ó rú sí Olúwa Ọlọ́run wa yóò jẹ́ ohun ìríra sí àwọn ará ilẹ̀ Ejibiti. Bí a bá ṣe ìrúbọ ti yóò jẹ́ ìríra ni ojú wọn ṣé wọn, ó ní sọ òkúta lù wá? 27A gbọdọ̀ lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú aginjù láti rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wa.” 28Nígbà náà ni Farao wí pé, “Èmi yóò jẹ́ ki ẹ lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín nínú aginjù, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rìn jìnnà jù. Ẹ gbàdúrà fún mi.” 29Mose dáhùn ó wí pé, “Bí èmi bá ti kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa, àwọn ọ̀wọ́ eṣinṣin yóò fi Farao, àwọn ìjòyè rẹ, àti àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀ ní ọ̀la ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ìdánilójú wa pé Farao kò tún ni lo ẹ̀tàn láti má jẹ́ kí àwọn ènìyàn kí ó lọ rú ẹbọ sí Olúwa.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.