Native Bible

Exodus 6:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmí sì tún fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú wọn láti fún wọn ní ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí wọn gbé gẹ́gẹ́ bí àjèjì.

Exodus 6:4 in English

Exodus 6:4 · Berean Standard Bible

I also established My covenant with them to give them the land of Canaan, the land where they lived as foreigners.

Context

2Ọlọ́run sì tún sọ fún Mose pé, “Èmi ni Olúwa. 3Mo fi ara hàn Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu bí Ọlọ́run alágbára, ṣùgbọ́n nípa orúkọ mi Olúwa, Èmi kò fi ara mi hàn wọ́n. 4Èmí sì tún fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú wọn láti fún wọn ní ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí wọn gbé gẹ́gẹ́ bí àjèjì. 5Èmi sì ti tún gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Israẹli àwọn tí àwọn ará Ejibiti mú gẹ́gẹ́ bí ẹrú, àti pé èmi sì ti rántí májẹ̀mú mi. 6“Sọ fún àwọn ará ilé Israẹli, ‘Èmi ni Olúwa, Èmi yóò sọ yín di òmìnira kúrò nínú àjàgà àwọn ará Ejibiti. Èmi yóò sì gbà yín sílẹ̀ kúrò ní oko ẹrú wọn. Èmi yóò dá a yín sílẹ̀ pẹ̀lú apá nínà (àwọn iṣẹ́ ìyanu) àti pẹ̀lú ìdájọ́ ńlá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.