Native Bible

Exodus 39:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó ṣiṣẹ́ òkúta óníkìsì tí a tò sí ojú ìdè wúrà, tí a sì fín wọn gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọ Israẹli.

Exodus 39:6 in English

Exodus 39:6 · Berean Standard Bible

They mounted the onyx stones in gold filigree settings, engraved like a seal with the names of the sons of Israel.

Context

4Ó ṣe aṣọ èjìká fún ẹ̀wù efodu náà, èyí tí ó so mọ igun rẹ̀ méjèèjì, nítorí kí ó lè so ó pọ̀. 5Ọnà ìgbànú híhun rẹ̀ rí bí i ti rẹ̀ ó rí bákan náà pẹ̀lú ẹ̀wù efodu ó sì sé e pẹ̀lú wúrà, àti pẹ̀lú aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. 6Ó ṣiṣẹ́ òkúta óníkìsì tí a tò sí ojú ìdè wúrà, tí a sì fín wọn gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọ Israẹli. 7Ó sì so wọ́n mọ́ aṣọ èjìká ẹ̀wù efodu náà bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. 8Ó ṣe iṣẹ́ ọnà sí ìgbàyà náà iṣẹ́ ọgbọ́n ọlọ́nà. Ó ṣe é bí ẹ̀wù efodu: ti wúrà ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.