Native Bible

Exodus 38:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì ṣe àgbàlá inú náà. Ní ìhà gúúsù ni aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára wà, ó jẹ́ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ní gígùn,

Exodus 38:9 in English

Exodus 38:9 · Berean Standard Bible

Then he constructed the courtyard. The south side of the courtyard was a hundred cubits long * and had curtains of finely spun linen,

Context

7Ó sì fi òpó náà bọ inú òrùka, nítorí kí ó lè wà ní ìhà pẹpẹ náà láti máa fi gbé e. Ó sì fi pákó ṣé pẹpẹ náà ní oníhò nínú. 8Ó ṣe agbada idẹ, o sì fi idẹ ṣe ẹsẹ̀ rẹ̀ ti àwòjìji àwọn obìnrin tí ó ń sìn ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. 9Ó sì ṣe àgbàlá inú náà. Ní ìhà gúúsù ni aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára wà, ó jẹ́ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ní gígùn, 10pẹ̀lú ogún òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, àti pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà. 11Ní ìhà àríwá náà tún jẹ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ní gígùn, ó sì ní ogún òpó àti ogun ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.