Eksodu 38:3
Exodus 38:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Idẹ ni ó ṣe gbogbo ohun èlò pẹpẹ, ìkòkò rẹ̀, ọkọ, àwokòtò rẹ̀, fọ́ọ̀kì tí a fi n mú ẹran àti àwo iná rẹ̀.
Exodus 38:3 in English
Exodus 38:3 · Berean Standard Bible
He made all the altar’s utensils of bronze—its pots, shovels, sprinkling bowls, meat forks, and firepans.
Context
1Ó sì fi igi kasia kọ́ pẹpẹ ẹbọ sísun, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ni gíga rẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, igun rẹ̀ ṣe déédé. 2Ó ṣe ìwo sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, nítorí kí ìwo àti pẹpẹ náà lè jẹ́ ọ̀kan, ó sì bo pẹpẹ náà pẹ̀lú idẹ. 3Idẹ ni ó ṣe gbogbo ohun èlò pẹpẹ, ìkòkò rẹ̀, ọkọ, àwokòtò rẹ̀, fọ́ọ̀kì tí a fi n mú ẹran àti àwo iná rẹ̀. 4Ó ṣe ààrò fún pẹpẹ náà, àwọ̀n onídẹ, kí ó wà níṣàlẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, dé ìdajì òkè pẹpẹ náà. 5Ó dá òrùka idẹ láti mú kí ó di òpó igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin idẹ ààrò náà mú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.