Eksodu 37:10
Exodus 37:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó ṣe tábìlì igi ṣittimu ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní gíga.
Exodus 37:10 in English
Exodus 37:10 · Berean Standard Bible
He also made the table of acacia wood two cubits long, a cubit wide, and a cubit and a half high.*
Context
8Ó ṣe kérúbù kan ní igun kìn-ín-ní, àti kérúbù kejì sí igun kejì; kí kérúbù náà jẹ́ irú kan náà ní igun méjèèjì pẹ̀lú ìbòrí wọn. 9Àwọn kérúbù sì na ìyẹ́ apá wọn sókè, tí wọn yóò sì fi ìyẹ́ apá wọn ṣe ibòòji sí orí ìtẹ́ àánú. Àwọn kérúbù náà yóò kọ ojú sí ara wọn, wọn yóò máa wo ọ̀kánkán ìtẹ́. 10Ó ṣe tábìlì igi ṣittimu ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní gíga. 11Ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí i ká. 12Ó sì ṣe etí kan ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ sí i yíká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.