Native Bible

Exodus 34:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n Mose pè wọn; Aaroni àti gbogbo àwọn olórí àjọ padà wá bá a, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀.

Exodus 34:31 in English

Exodus 34:31 · Berean Standard Bible

But Moses called out to them; so Aaron and all the leaders of the congregation returned to him, and Moses spoke to them.

Context

29Nígbà tí Mose sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Sinai pẹ̀lú wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀, òun kò mọ̀ pé ojú òun ń dán nítorí ó bá Olúwa sọ̀rọ̀. 30Nígbà tí Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí Mose, ojú rẹ̀ ń dán, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti súnmọ́ ọn. 31Ṣùgbọ́n Mose pè wọn; Aaroni àti gbogbo àwọn olórí àjọ padà wá bá a, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀. 32Lẹ́yìn èyí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli súnmọ́ ọn, ó sì fún wọn ní gbogbo àṣẹ tí Olúwa fún un lórí òkè Sinai. 33Nígbà tí Mose parí ọ̀rọ̀ sísọ fún wọn. Ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.