Native Bible

Exodus 34:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Àjọ àkàrà àìwú ni kí ìwọ máa pamọ́. Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò jẹ àkàrà aláìwú, gẹ́gẹ́ bí Èmi ti pa á láṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní ìgbà tí a yàn nínú oṣù Abibu, nítorí ní oṣù náà ni ẹ jáde láti Ejibiti wá.

Exodus 34:18 in English

Exodus 34:18 · Berean Standard Bible

You are to keep the Feast of Unleavened Bread.* For seven days at the appointed time in the month of Abib,* you are to eat unleavened bread as I commanded you. For in the month of Abib you came out of Egypt.

Context

16Nígbà tí ìwọ bá yàn nínú àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ ní ìyàwó, àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí yóò ṣe àgbèrè tọ òrìṣà wọn, wọn yóò sì mú kí àwọn ọmọkùnrin yín náà ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. 17“Ìwọ kò gbọdọ̀ dá ère òrìṣàkórìṣà fún ara rẹ. 18“Àjọ àkàrà àìwú ni kí ìwọ máa pamọ́. Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò jẹ àkàrà aláìwú, gẹ́gẹ́ bí Èmi ti pa á láṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní ìgbà tí a yàn nínú oṣù Abibu, nítorí ní oṣù náà ni ẹ jáde láti Ejibiti wá. 19“Gbogbo àkọ́bí inú kọ̀ọ̀kan tèmi ní i ṣe, pẹ̀lú àkọ́bí gbogbo ohun ọ̀sìn rẹ, bóyá ti màlúù tàbí ti àgùntàn. 20Àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni kí ìwọ kí ó fi ọ̀dọ́-àgùntàn rà padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, dá ọrùn rẹ̀. Ra gbogbo àkọ́bí ọkùnrin rẹ padà. “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá síwájú mi ní ọwọ́ òfo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.